Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn àpẹẹrẹ láti ọwọ́ Josephus: Ní Òke Sínáì mànàmáná àti àrá “fi hàn pé Ọlọ́run wà [pa·rou·siʹa] níbẹ̀.” Ìfarahàn lọ́nà ìyanu nínú àgọ́ àjọ “fi wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] Ọlọ́run hàn.” Nípa fífi àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ó pagbo yí wọn ká han ìránṣẹ́ Èlíṣà, Ọlọ́run “fi agbára àti wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀ hàn fún ìránṣẹ́ rẹ̀.” Nígbà tí ìjòyè òṣìṣẹ́ Róòmù Petronius gbìyànjú láti tu àwọn Júù lójú, Josephus sọ pé ‘Ọlọ́run fi wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀ hàn fún Petronius, nípa rírọ̀jò. Josephus kò lo pa·rou·siʹa fún sísún mọ́lé lásán tàbí dídé ní àkókò pàtó. Ó túmọ̀ sí wíwà níhìn-ín tí ń bá a nìṣó, àní tí a kò lè fojú rí. (Ẹ́kísódù 20:18-21; 25:22; Léfítíkù 16:2; Àwọn Ọba Kejì 6:15-17)—Fi wé Antiquities of the Jews, Ìwé 3, orí 5, ìpínrọ̀ 2 [80]; orí 8, ìpínrọ̀ 5 [202]; Ìwé 9, orí 4, ìpínrọ̀ 3 [55]; Ìwé 18, orí 8, ìpínrọ̀ 6 [284].