Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn tó ń ṣèwádìí ti fojú bù ú pé, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tó ń gbé nílùú Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì, pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000] sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] nígbà ayé Jónà, ìyẹn ò sì tó ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tó ń gbé nílùú Nínéfè. Nígbà tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù nílùú Nínéfè, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìlú yẹn ló tóbi jù lọ láyé ìgbà yẹn.