Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn ará Gíríìkì kan tó ń jẹ́ Herodotus, sọ pé nígbà táwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ológun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àtàwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ yẹn níbàámu pẹ̀lú àṣà wọn.