Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ibi gíga tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà ni Ásà mú kúrò, kì í ṣàwọn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n tún àwọn ibi gíga míì kọ́ lọ́wọ́ ìparí ìṣàkóso Ásà, kó wá jẹ́ pé Jèhóṣáfátì ọmọ ẹ̀ ló wá mú àwọn yẹn kúrò.—1 Ọba 15:14; 2 Kíró. 15:17.