Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a “Ẹyín iná” ń tọ́ka sí ọ̀nà kan tí wọ́n máa ń gbà yọ́ irin nígbà àtijọ́. Wọ́n á kó ẹyín iná sókè irin náà àti sí abẹ́ rẹ̀ kí ìdàrọ́ inú rẹ̀ lè kúrò kó sì ṣẹ́ ku èyí tó jẹ́ ojúlówó. Bí a bá ń fi inú rere hàn sáwọn tí kò níwà rere, èyí lè mú kí wọ́n yíwà pa dà kí wọ́n sì máa hùwà tó dáa.