Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọjọ́ yìí lè máà bá ọjọ́ tí àwọn Júù òde òní ń ṣe Ìrékọjá wọn mu. Kí nìdí? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù òde òní máa ń ṣe Ìrékọjá ní Nísàn 15, ìgbàgbọ́ wọn ni pé ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run ń tọ́ka sí nígbà tó pa àṣẹ tó wà nínú Ẹ́kísódù 12:6. (Ka Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1990, ojú ìwé 14.) Àmọ́, Nísàn 14 ni Jésù ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ohun tí Òfin Mósè sọ. Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí a ṣe lè ka ọjọ́ yìí, ka Ile-Iṣọ Na December 15, 1977 ojú ìwé 767 sí 768.