Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Léfítíkù 19:18 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé àwọn Júù nìkan làwọn gbólóhùn náà, “ọmọ àwọn ènìyàn rẹ” àti “ọmọnìkejì rẹ” ń tọ́ka sí. Òfin béèrè pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. Àmọ́, kò fara mọ́ èrò táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ọ̀rúndún kìíní ń gbé lárugẹ, pé ọ̀tá àwọn ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Júù àti pé ó yẹ kí àwọn kórìíra wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.