Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lérò pé gbólóhùn náà “awọ fún awọ” lè túmọ̀ sí pé Jóòbù kò ní bìkítà bí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹran rẹ̀ bá pàdánù ẹran ara wọn, tàbí ìwàláàyè wọn, bí ohunkóhun kò bá ṣáà ti ṣẹlẹ̀ sí ẹran ara, tàbí ìwàláàyè tirẹ̀. Àwọn mìíràn lérò pé ńṣe ni gbólóhùn náà ń tẹnu mọ́ ọn pé ẹnì kan á múra tán láti pàdánù díẹ̀ lára ẹran ara rẹ̀ bó bá jẹ́ pé ọ̀nà tó fi lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá fẹ́ fi ohun kan gbá ẹnì kan lórí, ó lè na apá rẹ̀ sókè láti fi gba nǹkan náà dúró, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù díẹ̀ lára awọ apá rẹ̀ kó lè dáàbò bo awọ orí rẹ̀. Ohun yòówù kí àkànlò èdè náà túmọ̀ sí, ó ṣe kedere pé ohun tó ń sọ ni pé inú Jóòbù máa dùn láti pàdánù gbogbo ohun tó ní kó lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là.