Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
e Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti sọ ìpinnu wọn lórí ẹjọ́ náà, ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣì fẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù bá àwọn tún ẹjọ́ náà gbọ́. Àmọ́, ní November 22, 2010, ìgbìmọ̀ tó ní àwọn adájọ́ márùn-ún nínú yìí, kò fara mọ́ ìwé tí wọ́n kọ láti béèrè pé kí wọ́n bá àwọn tún ẹjọ́ náà gbọ́. Torí náà, kò sí ohun tó lè yí ìdájọ́ tó ti kọ́kọ́ wáyé ní June 10, 2010 pa dà, ìyẹn sì ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà gbọ́dọ̀ fara mọ́.