Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Bí àpẹẹrẹ, ìwé Tobit (tàbí Tobias), táwọn kan rò pé ó jẹ́ apá kan Bíbélì jẹ́ ọ̀kan lára irú ìtàn èké bẹ́ẹ̀. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́, tó fi hàn pé ó ti wà nígbà ayé Pọ́ọ̀lù. Ìwé náà sọ ọ̀pọ̀ ìtàn nípa ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán, àwọn ìtàn tí kò bọ́gbọ́n mu nípa idán pípa àti iṣẹ́ oṣó lọ́nà tó fi dà bíi pé òótọ́ ni wọ́n ṣẹlẹ̀.—Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 122.