Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Jésù àtàwọn àpọ́sítélì sọ pé àwọn ọkùnrin kan máa dìde nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n á sì máa kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èké. (Mátíù 13:24-30, 36-43; 2 Tímótì 4:3; 2 Pétérù 2:1; 1 Jòhánù 2:18) Ọ̀rọ̀ yìí wá rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì ọgọ́rùn-ún ọdún kejì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba àṣà àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n sì ń da ẹ̀kọ́ Bíbélì pọ̀ mọ́ ọgbọ́n orí ilẹ̀ Gíríìsì.