Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Béárì aláwọ̀ ilẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Síríà, tí wọ́n máa ń rí ní Palẹ́sìnì nígbà kan, wúwo tó ogóje [140] kìlógíráàmù, ó sì lè fi ọwọ́ rẹ̀ pàǹpà tó ní èékánná pa èèyàn àti ẹranko. Ìgbà kan wà tí kìnnìún pọ̀ lágbègbè yẹn. Aísáyà 31:4 sọ pé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn olùṣọ́ àgùntàn” kò ní lè lé “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀” kúrò nídìí ẹran tó fẹ́ jẹ.