Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé wà fún gbogbo àwọn ọdún tí wọ́n sọ pé àwọn ọba Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì fi ṣàkóso. Nígbà tí wọ́n ṣe àròpọ̀ gbogbo iye ọdún tí àwọn ọba wọ̀nyí fi ṣàkóso, tí wọ́n wá kà á pa dà sẹ́yìn látọ̀dọ̀ Nábónídọ́sì tó ṣàkóso kẹ́yìn ní Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì, ọdún tí wọ́n sọ pé wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run yóò wá bọ́ sí ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí máa jóòótọ́ kìkì tí àwọn ọba náà bá jẹ tẹ̀ lé ara wọn ní ọdún kan náà láìsí àlàfo kankan láàárín wọn.