Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Èdè Nahuatl wá látinú èdè Uto-Aztec tó pín sí oríṣiríṣi tó sì jẹ́ èyí tí àwọn ẹ̀yà bíi Hopi, Shosone àti Comanche tó wà ní Amẹ́ríkà ti Àríwá ń sọ. Inú èdè Nahuatl ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ti yá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pe èso píà, ìyẹn avocado, àti ṣokoléètì àti tòmátì àti orúkọ ẹranko náà coyote.