Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà náà, ìyẹn ní ọdún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pín sí ìjọba méjì. Ọ̀kan ni ìjọba Júdà tó jẹ́ ẹ̀yà méjì tó wà níhà gúúsù. Ìkejì ni ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà níhà àríwá, èyí tí wọ́n tún ń pè ní Éfúráímù torí pé ẹ̀yà náà ló gba iwájú láàárín wọn.