Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀rọ̀ náà “àpókírífà” jẹ́ ọ̀rọ̀ kan lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “fi pa mọ́ sí ìkọ̀kọ̀.” Ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ń lo ọ̀rọ̀ náà fún látijọ́ ni ìwé ìkọ̀kọ̀ kan tó wà fún kìkì àwọn tó jọ ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìkọ̀kọ̀ yẹn, wọn kì í sì í jẹ́ kí ọ̀gbẹ̀rì tí kò bá sí nínú ẹgbẹ́ wọn rí i sójú rárá. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ yẹn pe àwọn ìwé kan tí wọn kò kà mọ́ ara àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú Bíbélì.