Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn akọ̀wé kan ní ayé ìgbàanì yí ẹsẹ yìí sí “ọkàn mi,” bíi pé Jeremáyà ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí. Ṣe ni wọ́n gbà pé ó máa bu Ọlọ́run kù tí a bá sọ pé ó jẹ́ ọkàn, torí ọ̀rọ̀ yẹn ni Bíbélì máa ń lò fún àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí inú ayé. Àmọ́ Bíbélì sábà máa ń fi ohun tó jẹ mọ́ àwa èèyàn júwe Ọlọ́run kí ohun tó ń sọ lè tètè yé wa. Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lè túmọ̀ sí “ìwàláàyè wa,” nítorí náà, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn rẹ” túmọ̀ sí “ìwọ” fúnra rẹ.