Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236]. Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lo wákàtí tí ó tó bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù méje lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì kọ́ àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́jọ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.