Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ baba wa pọ̀ gan-an nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “Baba” ní nǹkan bí ìgbà márùnlélọ́gọ́ta [65] nínú ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù, Máàkù àti Lúùkù, ó sì lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ìgbà tó lò ó nínú Ìhìn Rere ti Jòhánù. Ó ju ogójì [40] ìgbà lọ tí Pọ́ọ̀lù náà pe Ọlọ́run ní “Baba” nínú àwọn ìwé tó kọ. Jèhófà ni Baba wa ní ti pé òun ló fún wa ní ìwàláàyè wa.