ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

a Bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà kò bá pọ̀ tó iye tí wọ́n fi lè jẹ́ kíláàsì kan, a lè pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ní ọdún márùn-ún sígbà yẹn láti kún wọn.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọ kí wọ́n sì lè mọ púpọ̀ sí i nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa sin Jèhófà.

Àkókò: Ọjọ́ márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alàgbà.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa pe àwọn alàgbà tó bá kúnjú ìwọ̀n.

Ohun tí àwọn kan tó lọ sí kíláàsì kejìléláàádọ́rùn-ún lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ rèé:

“Mo ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an ní ilé ẹ̀kọ́ náà, ó ti mú kí n máa kíyè sí bí mo ṣe ń ṣe sí kí n sì máa ronú nípa bí mo ṣe lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà.”

“Mo ti ṣe tán báyìí láti máa fún àwọn èèyàn níṣìírí nípa ṣíṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Ìwé Mímọ́.”

“Mi ò jẹ́ gbàgbé ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Àtàwọn Ìyàwó Wọn

Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alábòójútó àgbègbè máa ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ lọ́nà tó túbọ̀ múná dóko, bí wọ́n ti ń “ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.”—1 Tím. 5:17; 1 Pét. 5:2, 3.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu rẹ̀.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ alábòójútó àyíká tàbí alábòójútó àgbègbè.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn.

Joel tó lọ sí kíláàsì àkọ́kọ́ ní ọdún 1999 sọ pé: “Ó ti mú ká túbọ̀ mọyì bí Jésù ṣe ń darí ètò Ọlọ́run. A rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fún àwọn ará tí à ń bẹ̀ wò ní ìṣírí kí a sì mú kí ìjọ kọ̀ọ̀kan túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí gbìn ín sí wa lọ́kàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń fún àwọn ará nímọ̀ràn tó sì máa ń sọ àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe nígbà míì, ìdí pàtàkì tó fi ń ṣe ìbẹ̀wò sáwọn ìjọ ni pé kó lè mú kó dá àwọn ará lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n

Ohun Tó Wà Fún: Láti mú kí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí kò tíì gbéyàwó wà ní ìmúratán láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa ń rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n lè rán àwọn míì lọ sìn lórílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè ní kí àwọn kan lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n lè lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tó jìnnà àti láwọn ibi àdádó, kí wọ́n sì lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò níbẹ̀.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu; ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin tí kò níyàwó tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí ọdún méjìlélọ́gọ́ta [62], tó ní ìlera tó dáa, tó sì fẹ́ lọ sìn níbikíbi tá a bá ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Máàkù 10:29, 30) Ó kéré tán, ó ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún ọdún méjì, ó sì ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọdún méjì láìdáwọ́dúró.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: A máa ń ṣe ìpàdé kan nígbà àpéjọ àyíká láti pèsè ìsọfúnni fún àwọn tó bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Rick tó lọ sí kíláàsì kẹtàlélógún [23] ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Bí mo ṣe ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ni ẹ̀mí Jèhófà túbọ̀ ń mú kí n ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ìgbésí ayé mi. Bí Jèhófà bá gbé iṣẹ́ lé èèyàn lọ́wọ́, kì í dá onítọ̀hún dá irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pe Ọlọ́run máa fún mi lókun tí n bá gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀.”

Andreas tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Látàrí ohun tí mo kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, iṣẹ́ ìyanu ni ètò tí Ọlọ́run ń lò lóde òní jọ lójú mi. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà mú kí n gbára dì fún iṣẹ́ tó wà níwájú. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì fi òótọ́ pàtàkì kan kọ́ mi. Ìyẹn ni pé: Tí mo bá ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà tí mo sì ń lo ara mi fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi, ó dájú pé màá ní ojúlówó ayọ̀.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya

Ohun Tó Wà Fún: Láti fún àwọn tọkọtaya ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe, kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege la máa rán lọ sí àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwáàsù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. A lè ní kí àwọn kan lọ sìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ náà lè lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n lè lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tó jìnnà àti láwọn ibi àdádó, kí wọ́n sì lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò níbẹ̀.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà báyìí, àmọ́ láti oṣù September, ọdún 2012, ó máa bẹ̀rẹ̀ ní àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan kárí ayé. Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ la ti sábà máa ń ṣe é.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sí àádọ́ta [50] ọdún, tí wọ́n ní ìlera tó dáa, tí ipò wọn sì yọ̀ǹda fún wọn láti lọ sìn ní ibikíbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, tí wọ́n sì ní irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní, nígbà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Ó kéré tán, wọ́n ti gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó fún ọdún méjì kí wọ́n sì ti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán. Ọkọ ti gbọ́dọ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìdáwọ́dúró fún ọdún méjì, ó kéré tán.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: A máa ń ṣe ìpàdé kan nígbà àpéjọ àgbègbè láti pèsè ìsọfúnni fún àwọn tó bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Bí wọn kì í bá ṣe irú ìpàdé yìí ní àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè rẹ, tó o sì fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, o lè kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kó o lè gba ìsọfúnni síwájú sí i.

“Ńṣe ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀-mẹ́jọ yìí ń yí ìgbé ayé ẹni pa dà, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ fún àwọn tọkọtaya tó bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! Ìpinnu wa ni pé a ó máa gbé ìgbé ayé tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ká lè máa fi ọgbọ́n lo àkókò wa.”—Eric àti Corina (nínú àwòrán ojú ìwé yìí), kíláàsì àkọ́kọ́, ọdún 2011.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Ohun Tó Wà Fún: Láti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa sìn ní pápá bíi míṣọ́nnárì láwọn àgbègbè táwọn èèyàn pọ̀ sí gan-an, kí wọ́n lè máa sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì. A dìídì ṣètò ilé ẹ̀kọ́ yìí láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i, kí àbójútó gidi sì lè wà ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé.

Àkókò: Oṣù márùn-ún.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe, bóyá àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá tí wọn kò tíì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ó kéré tán, wọ́n ti gbọ́dọ̀ jọ wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́nà àkànṣe fún ọdún mẹ́ta láìdáwọ́dúró. Wọ́n gbọ́dọ̀ lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n lè kà á, kí wọ́n sì lè kọ ọ́ dáadáa.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tí tọkọtaya kan ti ń sìn lè ní kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù ilé ẹ̀kọ́ yìí.

Lade àti Monique tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń sìn báyìí ní ilẹ̀ Áfíríkà. Lade sọ pé: “Pẹ̀lú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí, kò sí ibi tí a kò lè lọ láyé yìí, a ti múra tán láti lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa ọ̀wọ́n.”

Monique náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń fi àwọn nǹkan tí mo ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, bẹ́ẹ̀ ni mò ń láyọ̀ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi. Ayọ̀ tí mo ní yìí ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn

Ohun Tó Wà Fún: Láti ran àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa ṣe àbójútó àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n máa fún àwọn ọ̀ràn iṣẹ́ ìsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìjọ láfiyèsí, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn àyíká àti àgbègbè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Wọ́n tún ń fún wọn ní ìsọfúnni nípa iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, ìwé títẹ̀ àti kíkó ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ.

Àkókò: Oṣù méjì.

Ibi Tí A Ti Ń Ṣe É: Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní ìlú Patterson, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ohun Téèyàn Gbọ́dọ̀ Dójú Ìlà Rẹ̀: Arákùnrin náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè tàbí àwọn tí wọ́n bá yàn láti máa ṣe ojúṣe yìí.

Béèyàn Ṣe Lè Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń pe àwọn arákùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n àtàwọn ìyàwó wọn.

Lowell àti Cara, tí wọ́n lọ sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ti ń sìn báyìí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lowell sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí bí ọwọ́ mi ṣe lè dí tó tàbí iṣẹ́ yòówù kí wọ́n gbé fún mi, ohun pàtàkì tó lè jẹ́ kí n mú inú Jèhófà dùn ni pé kí n máa ṣe nǹkan lọ́nà tó wù ú. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn tún jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.”

Cara náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ kan tí mo sábà máa ń ronú lé lórí ni pé, tí mi ò bá ti lè ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ kan lọ́nà tó rọrùn, àfi kí n fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dáadáa kí n tó fi kọ́ ẹlòmíì.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́