Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Dáníẹ́lì kò rí Ọlọ́run ní ti gidi. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni Ọlọ́run mú kó rí àwọn ohun kan kedere lójú ìran. Nígbà tí Dáníẹ́lì wá ń ṣàpèjúwe ohun tí ó rí, ó lo àwọn ẹ̀yà ara èèyàn àti ìṣe èèyàn láti fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Irú àwọn èdè àpèjúwe bẹ́ẹ̀ mú kí á lè ní òye irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àmọ́ kì í ṣe pé kí a máa wá rò pé bí ìrísí Ọlọ́run ṣe rí gẹ́lẹ́ náà nìyẹn.