Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé abirùn ọmọ ni wọ́n máa fi oyún náà bí ńkọ́? Tàbí, tó bá fi hàn pé wọn máa fi oyún náà bí ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ ńkọ́? Bí tọkọtaya kan bá fọwọ́ sí i pé kí dókítà mú kí oyún náà wálẹ̀, a jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́yún nìyẹn. Nítorí pé ọgbọ́n ìṣègùn yìí máa ń mú kí wọ́n gbé ọlẹ̀ tó ju ẹyọ kan lọ sínú obìnrin, ó sábà máa ń mú kí wọ́n ní oyún ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí léwu gan-an, ó lè mú kí obìnrin náà bímọ ní kògbókògbó tàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa dà lára rẹ̀. Tí obìnrin kan bá ní oyún ìbejì tàbí iye ọmọ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn dókítà lè rọ̀ ọ́ pé kó jẹ́ káwọn pa ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ọlẹ̀ náà. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́yún. Wọ́n sì ti di apààyàn nìyẹn.—Ẹ́kís. 21:22, 23; Sm. 139:16.