Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “pípilẹ̀ ayé” níhìn-ín jẹ mọ́ fífúnrúgbìn, èyí tó máa túmọ̀ sí mímú irú ọmọ jáde. Ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí àkọ́kọ́ nínú irú ọmọ ẹ̀dá èèyàn. Kí nìdí tó fi wá jẹ́ pé Ébẹ́lì ni Jésù fi “ìgbà pípilẹ̀ ayé” tọ́ka sí dípò Kéènì tó jẹ́ ọmọ àkọ́kọ́ tí wọ́n bí ní ayé? Ìdí ni pé, ìwà Kéènì àti ìpinnu rẹ̀ fi hàn pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Kéènì wá dà bí ti àwọn òbí rẹ̀, torí kò jọ pé ó wà lára àwọn tó máa ní àjíǹde àti àwọn tó lè rí ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ gbà.