Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Wọ́n sábà máa ń fi orúkọ àwọn tí wọ́n gbà pé ó lóye ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ tí Jésù kọ́ni dunjú pe àwọn ìwé ìhìn rere yẹn. Irú bí èyí tí wọ́n pè ní Ìhìn Rere Tọ́másì, àti Ìhìn Rere Màríà Magidalénì. Nǹkan bí ọgbọ̀n irú ìwé àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó ń ṣe ìwádìí ti rí.