Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àpèjúwe Jésù máa ń bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àṣà àti ìṣe àwọn èèyàn mu. Ojúṣe pàtàkì ni àwọn Júù ka ṣíṣe àlejò sí. Ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe búrẹ́dì púpọ̀ lóòjọ́, torí náà àwọn Júù sábà máa ń tọrọ lọ́wọ́ ara wọn tí búrẹ́dì wọn bá tán. Bákan náà, tí wọ́n bá jẹ́ tálákà, ilẹ̀ ni gbogbo ìdílé náà máa sùn sí nínú yàrá kan ṣoṣo.