Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Orúkọ àrùn náà LMBB jẹ́ ìkékúrú Laurence-Moon-Bardet-Biedl. Orúkọ àwọn dókítà mẹ́rin tí wọ́n ṣe ìwádìí àrùn yìí ni wọ́n fi sọ orúkọ àrùn náà. Wọ́n sọ pé ohun tó máa ń fa àrùn yìí ni ìṣòro tó bá àwọn èròjà tó ń para pọ̀ di ọmọ inú oyún, èyí tó wá látara bàbá àti ìyá ọmọ náà. Ní báyìí, orúkọ tí wọ́n ń pe àrùn náà ni àrùn Bardet-Biedl. Àrùn náà ò sì gbóògùn.