Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ìpínrọ̀ 8: Ọ̀kan lára ohun tí àwọn ẹsẹ yìí sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni bí Jésù ṣe máa “kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀.” (Mát. 24:31) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ jọ pé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá la máa gbé gbogbo ẹni àmì òróró tó bá ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé máa gòkè re ọ̀run, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ogun Amágẹ́dọ́nì máa jà. Àlàyé yìí ni kẹ́ ẹ fi sọ́kàn báyìí dípò èyí tá a ṣe nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1990, ojú ìwé 30.