Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
f Ìpínrọ̀ 16: Ìwé Dáníẹ́lì 12:3 sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró] yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú.” Nígbà tí wọ́n bá ṣì wà láyé, wọ́n á máa tàn yòò bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ìgbà tí wọ́n máa tàn yòò nínú Ìjọba ọ̀run ni Mátíù 13:43 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a rò pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.