Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
e Ìpínrọ̀ 13: Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Ìṣe 20:29, 30 fi hàn pé ọ̀nà méjì ni àtakò sí ìjọ Kristẹni á ti wá. Àkọ́kọ́, àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà (ìyẹn “àwọn èpò”) máa “wọlé wá sáàárín” àwọn Kristẹni tòótọ́. Èkejì, “láàárín” àwọn Kristẹni tòótọ́, àwọn kan máa di apẹ̀yìndà, wọ́n á máa sọ àwọn “ohun àyídáyidà.”