Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run mú kí ara àwọn ẹranko yẹn balẹ̀ lọ́nà kan ṣá, bóyá ṣe ni wọ́n kàn ń sùn, tó fi jẹ́ pé oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ mọ níwọ̀n. Bóyá bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa dáàbò bo gbogbo àwọn tó bá wà nínú ọkọ̀ áàkì, wọ́n á sì là á já.