Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn ilé gogoro tó dà bíi tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ ní ìpele-ìpele, ní àyíká ilẹ̀ Ṣínárì. Ìsàlẹ̀ àwọn ilé náà fẹ̀, òkè wọn sì rí ṣóńṣó. Bíbélì sọ pé bíríkì ni àwọn tó kọ́ ilé gogoro náà lò, kì í ṣe òkúta, wọ́n sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì ṣe erùpẹ̀ àpòrọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 11:3, 4) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The New Encyclopædia Britannica jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé nílẹ̀ Mesopotámíà yẹn, òkúta “kò fi bẹ́ẹ̀ sí tàbí kó má tiẹ̀ sí rárá,” àmọ́ ọ̀dà bítúmẹ́nì pọ̀ gan-an níbẹ̀.