Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ọlọ́run kórìíra kí tọkọtaya fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n tí ẹnì kan nínú wọn bá ṣe panṣágà, Ọlọ́run fún ẹnì kejì lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu bóyá kí òun kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Málákì 2:16; Mátíù 19:9) Àlàyé síwájú sí i wà nínú àkòrí náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà” nínú àfikún tó wà ní apá ìparí ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run, ojú ìwé 219-221. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.