Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣe 20:29, 30, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé láti àárín ìjọ Kristẹni ni “àwọn ènìyàn yóò . . . dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” Ìtàn jẹ́rìí sí i pé nígbà tó yá, ẹgbẹ́ àlùfáà àti ti ọmọ ìjọ bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Kristẹni, “ọkùnrin oníwà àìlófin” ti fara hàn. Òun la wá mọ̀ sí gbogbo àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lápapọ̀.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1990, ojú ìwé 10 sí 14.