Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀mọ̀wé ará Jámánì kan, Heinrich Meyer, sọ pé: “Níwọ̀n bí àwọn àlejò [àwọn àpọ́sítélì] ti rí i pé ara Jésù ṣì wà digbí (pé ó ṣì wà láàyè), àti pé, títí dìgbà yẹn, wọn ò tíì ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀, kò sí èyíkéyìí lára wọn tó jẹ́ gbà . . . ní ti gidi pé ara Olúwa làwọn ń jẹ àti pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gangan làwọn ń mu, [torí náà] Jésù Alára kò retí pé kí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí kò díjú lóye, torí pé wọn ò sọ́ fún un nígbà yẹn pé kò yé àwọn.”