Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé a Ìgbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá [12] nìkan la gbọ́ orúkọ Jósẹ́fù kẹ́yìn nínú Ìwé Ìhìn Rere. Lẹ́yìn ìyẹn, ìyá Jésù àti àwọn àbúrò rẹ̀ la tún ń gbọ́ orúkọ wọn. Kódà, wọ́n máa ń pe Jésù ní “ọmọkùnrin Màríà” láì tiẹ̀ mẹ́nu kan Jósẹ́fù.—Máàkù 6:3.