Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀gbẹ́ni Charles Darwin sọ nínú ìwé rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀yà ara wa ni kò “wúlò.” Ọ̀kan lára àwọn agbátẹrù rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé àìmọye irú àwọn ẹ̀yà ara yìí ló wà “tí wọ́n wulẹ̀ jẹ́ apá kan ẹ̀yà míì nínú ara,” irú bí apá kan tí wọ́n ń pè ní appendix àti ẹ̀yà kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbóguntàrùn inú ara, tí wọ́n ń pè ní thymus.—Ìwé The Descent of Man.