Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n máa ń ṣú opó, ìyẹn ni kí ọkùnrin kan fẹ́ ìyàwó ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ tó kú láìní ọmọkùnrin. Ọmọ tí ìyàwó náà bá bí á máa jẹ́ orúkọ ẹni tó kú náà kí ìdílé rẹ̀ má bàa pa run.—Jẹ́n. 38:8; Diu. 25:5, 6.