Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sapá láti mọ ohun tó ń fà á táwa èèyàn fi ń darúgbó tá a sì ń kú, àmọ́ ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures sọ nípa ìsapá wọn pé: “Wọ́n gbàgbé pé Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ ló dájọ́ ikú fún tọkọtaya àkọ́kọ́, ọ̀nà tó sì gbé e gbà kò lè yé ẹ̀dá láéláé.”—Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 247.