Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn Fáráò ayé àtijọ́ máa ń jẹ tó àádọ́rùn [90] oríṣi búrẹ́dì àti kéèkì. Torí náà, èèyàn pàtàkì ni ẹni tí wọ́n bá yàn ṣe olórí àwọn olùṣe búrẹ́dì. Ẹnì kejì tó jẹ́ olórí àwọn agbọ́tí ló máa ń mójú tó bí wọ́n ṣe ń ṣe wáìnì tàbí bíà tí Fáráò máa ń mu. Wáìnì náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ògidì, kò sì gbọ́dọ̀ ní májèlé nínú. Torí nígbà yẹn, wọ́n máa ń dìtẹ̀ ọba, wọ́n sì lè máa wá ọgbọ́n láti pa á. Ìdí nìyí tí agbọ́tí ọba fi sábà máa ń wà lára àwọn tí ọba fọkàn tán tó sì máa ń bá ọba dámọ̀ràn.