Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Cerebral palsy ni orúkọ gbogbo gbòò tí wọ́n fi ń ṣàpèjúwe àrùn inú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kéèyàn lè gbé apá àti ẹsẹ bó ṣe fẹ́. Ó tún lè fa gìrì, àìlè jẹun dáadáa àti àìlè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já geere. Spastic quadriplegia ló le jù lára àwọn àrùn cerebral palsy; ó lè mú kí gbogbo oríkèé ara kú tipiri, kì ọrùn sì máa gbọ̀n yèpéyèpé.