Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Lóòótọ́, àwọn nǹkan míì wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè dà bí i pé “ó nira láti lóye,” títí kan àwọn kan nínú àwọn ìwé Bíbélì tí Pọ́ọ̀lù kọ. Àmọ́, gbogbo àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ni ẹ̀mí mímọ́ mí sí. Ẹ̀mí mímọ́ yìí náà ló ń ran àwa Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ lónìí tá a fi ń lóye òtítọ́ Bíbélì, kódà ó ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” ó sì ń mú kó túbọ̀ ṣe kedere sí wa, bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé.—2 Pét. 3:16, 17; 1 Kọ́r. 2:10.