Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, Sátánì mú kí àwọn apẹ̀yìndà rú yọ, wọ́n sì gbòde kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Lákòókò yẹn, ọ̀pọ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ sapá mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ láti kó àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi jọ. Àmọ́, nǹkan máa yí pa dà nígbà “ìkórè,” ìyẹn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Mát. 13:24-30, 36-43) Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2013, ojú ìwé 9 sí 12.