Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìwé náà Manuscripts of the Greek Bible, sọ pé, Palaeography “jẹ́ ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ìwé ayé àtijọ́.” Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni ọ̀nà ìkọ̀wé máa ń yí pa dà. Àwọn àyípadà yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fojú bu ìgbà tí wọ́n kọ ìwé kan tí wọ́n bá fi wé àwọn ìwé míì tí wọ́n kọ láàárín àkókò kan náà.