Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Orin tí Dèbórà kọ fi hàn pé Sísérà máa ń kó oríṣiríṣi nǹkan bọ̀ látojú ogun, títí kan àwọn ọmọbìnrin. Nígbà míì ọmọ ogun kan lè gba ju ọmọbìnrin kan lọ. (Àwọn Onídàájọ́ 5:30) “Ilé ọlẹ̀” ni ẹsẹ Bíbélì yìí pe àwọn “ọmọbìnrin” tí wọ́n bá kó lẹ́rú. Èyí fi hàn pé torí kí wọ́n lè bá wọn lò pọ̀ ni wọ́n ṣe ń kó wọn lẹ́rú. Ìdí nìyẹn tí ìfipábánilòpọ̀ fi wọ́pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà.