Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ìtàn yìí kò dárúkọ Élíésérì, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni Ábúráhámù rán ní iṣẹ́ yìí. Ṣáájú kí Ábúráhámù tó bímọ tó máa jogún rẹ̀, ìgbà kan wà tó gbèrò láti kó gbogbo ogún rẹ̀ fún Élíésérì. Èyí fi hàn pé òun ló dàgbà jù tó sì ṣe é fọkàn tán jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù. Bí Bíbélì sì ṣe ṣàpèjúwe ẹni tí Ábúráhámù rán níṣẹ́ yìí nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 15:2; 24:2-4.