Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Tacitus, tí wọ́n bí ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni kọ̀wé pé “Kristi táwọn Kristẹni fi sọ ara wọn lórúkọ ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn baálẹ̀ wa dájọ́ ikú fún tí wọ́n sì pa nígbà ìjọba Tìbéríù.” Àwọn míì tó tún mẹ́nu kan Jésù ni Suetonius tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní; òpìtàn Júù náà Josephus tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti Pliny Kékeré tó jẹ́ gómìnà Bítíníà tó gbáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì.