Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1535, atúmọ̀ èdè ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó ń jẹ́ Olivétan tẹ ìtúmọ̀ Bíbélì tirẹ̀ jáde. Bíbélì tí wọ́n kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ló gbé ìtumọ̀ rẹ̀ kà. Àmọ́, ìtúmọ̀ Bíbélì tí Lefèvre ṣe ló gbára lé nígbà tó ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì.