Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jésù sọ àwọn àpèjúwe kan nígbà tó ń sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra lásìkò wíwàníhìn rẹ̀. Ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ táá máa múpò iwájú. (Mát. 24:45-47) Lẹ́yìn náà, ó sọ àwọn àpèjúwe tó kan gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso lọ́run. (Mát. 25:1-30) Ó wá parí rẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe nípa àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, táá sì máa ti àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́yìn. (Mát. 25:31-46) Bó ṣe rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì náà nìyẹn, lóde òní àwọn tó máa lọ sókè ọ̀run ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹ sí lára. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá máa ń tọ́ka sí àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, síbẹ̀, ìṣọ̀kan tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ jẹ́ ká rí i pé ìṣọ̀kan máa wà láàárín àwọn tó ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn tó ń retí àtilọ sọ́run.