Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ọbàkan Ábúráhámù ni Sárà. Térà ló bí àwọn méjèèjì, àmọ́ wọn kì í ṣọmọ ìyá kan náà. (Jẹ́nẹ́sísì 20:12) Irú ìgbéyàwó yìí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu lóde òní, àmọ́ ó yẹ ká rántí pé nǹkan ò rí bó ṣe rí báyìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ìdí ni pé àwọn èèyàn ṣì ní ìlera tó jí pépé, irú èyí tí Ádámù àti Éfà gbádùn àmọ́ tí wọ́n gbé sọnù. Fún àwọn èèyàn tó ní ìlera tó jí pépé, ìgbéyàwó láàárín ìbátan kò lè fa ìṣòro àìlera fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́ ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn náà, ẹ̀mí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kúrú bíi tiwa lóde òní. Torí náà, òfin tí Ọlọ́run fún Mósè nígbà yẹn kò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan.—Léfítíkù 18:6.