Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọ̀mọ̀wé kan ti fìgbà kan ṣe ìtúmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun ní èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù. Ọ̀kan lára wọn ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Simon Atoumanos, tó wá láti Byzantine, ní nǹkan bí ọdún 1360. Ẹlòmíì tó ṣe ìtúmọ̀ yìí ni Oswald Schreckenfuchs, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Jámánì ní nǹkan bí ọdún 1565. Wọn ò tẹ àwọn ìtúmọ̀ yìí jáde, wọ́n sì ti sọnù báyìí.